إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٞ 6
Dajudaju ọmọniyan paapaa jẹ olukọ rere eyiti Ọlọhun rẹ nfẹ lọdọ rẹ.
وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٞ 7
Dajudaju o si jẹ ẹlẹri lori kikọ rere rẹ, ko nikapa titako eleyi nitori hihan rẹ.
وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلۡخَيۡرِ لَشَدِيدٌ 8
Dajudaju o si tayọ nibi ifẹ rẹ si owo, ti o nse ahun pẹlu rẹ.
۞أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ 9
Se ọmọniyan ti o gba itanjẹ pẹlu aye yii ko mọ igbati Allah ba gbe awọn oku ti o wa ninu saare dide, ti o si mu wọn jade ninu ilẹ fun isiro ati ẹsan wipe ọrọ ko ri bi wọn se nlero rẹ?!
وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ 10
Ti wọn mu yọ ganbo, ti wọn si salaye awọn aniyan ati awọn adisọkan ati ohun ti o yatọ si i, ti o wa ninu awọn ọkan.
إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّخَبِيرُۢ 11
Dajudaju Ọlọhun wọn jẹ olufun wọn niro ni ọjọ yii, nkankan ko pamọ fun Un ninu ọrọ awọn ẹru Rẹ, yoo si san wọn lẹsan lori eleyi.
سورة (MAKIYYAH)
Kikan ọkan lati mu ipaya ọjọ igbende waye ati isesi awọn eniyan nibi awọn osunwọn.
ٱلۡقَارِعَةُ 1
Asiko eyiti yoo maa kan ọkan awọn eniyan nitori titobi ipaya rẹ.
مَا ٱلۡقَارِعَةُ 2
Kinni asiko eyiti o nkan ọkan awọn eniyan nitori titobi ipaya rẹ?!
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡقَارِعَةُ 3
Kinni o fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - kinni asiko yii eyiti o nkan ọkan awọn eniyan nitori titobi ipaya rẹ?! Dajudaju o jẹ ọjọ igbende.
يَوۡمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلۡفَرَاشِ ٱلۡمَبۡثُوثِ 4
Ọjọ ti wọn yoo maa kan ọkan awọn eniyan, ti wọn yoo si da gẹgẹ bi ajẹku koriko ti o fan ka niti fifanka ni ibiyi ati ni ọhun.
وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ٱلۡمَنفُوشِ 5
Ti awọn oke yoo si da gẹgẹ bi owu eyiti wọn ti lu ni onlu nibi fifuyẹ lilọ rẹ ati gbigbọn rẹ.
فَأَمَّا مَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ 6
Sugbọn ẹniti awọn isẹ rere ba tẹ wọn lori awọn isẹ aburu rẹ.
فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ 7
Oun ni yoo si maa wa ninu isẹmin iyọnu eyiti yoo ri ni ọgba idẹra.
وَأَمَّا مَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ 8
Sugbọn ẹniti awọn isẹ aburu ẹ ba tẹwọn lori awọn isẹ rere rẹ.
فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةٞ 9
Ibugbe rẹ ati ibusẹrisi rẹ ni ọjọ igbende jẹ ina jahannamọ.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا هِيَهۡ 10
Kinni o fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - ohun tii se?!
نَارٌ حَامِيَةُۢ 11
Ohun ni ina ti o gbona ni ooru.
سورة (MAKIYYAH)
Riran awọn ti wọn ko airoju pẹlu aye leti iku ati isiro nitori ẹ ni wọn fi sọ ni ọgba ọrọ awọn onisowo.
أَلۡهَىٰكُمُ ٱلتَّكَاثُرُ 1
Sise iyanran pẹlu awọn owo ati awọn ọmọ - ẹyin eniyan - ni o ko airoju ba yin nipa titẹle ti Allah.
حَتَّىٰ زُرۡتُمُ ٱلۡمَقَابِرَ 2
Ti ẹ fi ku, ti ẹ si fi wọ inu saare yin.
كَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ 3
Ko tọ fun yin ki iyanran ko airoju pẹlu yin nibi titẹle ti Allah, ẹ o pada mọ igbẹyin ikoroju yii.
ثُمَّ كَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ 4
Lẹyin naa ẹ o pada mọ igbẹyin rẹ.
كَلَّا لَوۡ تَعۡلَمُونَ عِلۡمَ ٱلۡيَقِينِ 5
paapaa ti ẹyin ba mọ amọdaju wipe wọn yoo gbe yin dide si ọdọ Allah atipe yoo san yin lẹsan lori awọn isẹ yin; sise iyanran pẹlu awọn dukia ati awọn ọmọ ki ba ti ku airoju ba yin.
لَتَرَوُنَّ ٱلۡجَحِيمَ 6
Mo fi Allah bura, ẹ o pada fi oju kan ina ni ọjọ igbende.
ثُمَّ لَتَرَوُنَّهَا عَيۡنَ ٱلۡيَقِينِ 7
Lẹyin naa paapaa ẹ o ri ni riri ti o daju, ti ko si iyemeji nibẹ.
ثُمَّ لَتُسَۡٔلُنَّ يَوۡمَئِذٍ عَنِ ٱلنَّعِيمِ 8
Paapaa Allah yoo bi yin leere ni ọjọ naa nipa idẹkun ti O se fun yin gẹgẹ bi alaafia ati ọrọ ati ohun ti o yatọ si wọn.
Ewu sise iyanran ati sise akọ pẹlu awọn duki ati awọn ọmọ.
Saare jẹ aaye ibẹwo kiakia nipa ibiti ọmọniyan yoo ti gbera lọsi ọrun.
Wọn yoo bi ọmọniyan leere nipa idẹkun eyiti Allah se le wọn lori ni ọjọ igbende.
Ọmọniyan jẹ ẹniti a jẹnipa lori ifẹ owo.