إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ فِي نَارِ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمۡ شَرُّ ٱلۡبَرِيَّةِ 6
Dajudaju awọn ti wọn se keferi - ninu yahuudi ati nasaara ati ninu awọn ẹlẹbọ - wọn yoo wọ ina jahannamọ ti wọn yoo wa nibẹ gbere ni ọjọ igbende, awọn wọnyi ni ẹniti o buru ju ni adamọ nitori keferi wọn si Allah ati irọ wọn si ojisẹ Rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أُوْلَٰٓئِكَ هُمۡ خَيۡرُ ٱلۡبَرِيَّةِ 7
Dajudaju awọn ti wọn nigbagbọ si Allah, ti wọn si nse awọn isẹẹre, awọn wọnyi ni wọn loore ni adamọ.
جَزَآؤُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ جَنَّٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ رَّضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَشِيَ رَبَّهُۥ 8
Ẹsan wọn wa lọdọ Ọlọhun wọn ti mimọ nbẹ fun, ohun si ni ọgba idẹra ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ati awọn igi rẹ, wọn yoo nibẹ gbere, Allah yoo yọnu si wọn nitori ohun ti wọn gbagbọ, ti wọn si tẹle e, awọn yoo yọnu nitori ikẹ Rẹ ti o de ọwọ wọn, ikẹ yii yoo de ọwọ ẹniti o ba paya Ọlọhun rẹ, ti o si mu asẹ Rẹ sẹ, ti o si jinna si ohun ti O kọ.
سورة (MADANIYYAH)
Kikan awọn ọkan olufọnu fun amọdaju nipa isiro ati amojuto finifini.
إِذَا زُلۡزِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ زِلۡزَالَهَا 1
Nigbati wọn ba min ilẹ ni minmin ti o le eyiti yoo sẹlẹ si i ni ọjọ igbende.
وَأَخۡرَجَتِ ٱلۡأَرۡضُ أَثۡقَالَهَا 2
Ti ilẹ si min jade ohun ti o wa ninu rẹ ninu awọn oku ati nkan miran.
وَقَالَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا لَهَا 3
Ti ọmọniyan si sọ ni ẹniti o ndaamun: kinni ohun ti o mun ilẹ ti o nmin, ti o si ngbọn?!
يَوۡمَئِذٖ تُحَدِّثُ أَخۡبَارَهَا 4
Ni ọjọ ti o tobi yii, ilẹ yoo maa mu iro ohun ti wọn se lori rẹ ni rere ati aburu wa.
بِأَنَّ رَبَّكَ أَوۡحَىٰ لَهَا 5
Nitoripe dajudaju Allah ni o fi eleyi mọ ọ, O si pa a lasẹ rẹ.
يَوۡمَئِذٖ يَصۡدُرُ ٱلنَّاسُ أَشۡتَاتٗا لِّيُرَوۡاْ أَعۡمَٰلَهُمۡ 6
Ni ọjọ ti o tobi yii, eyiti ilẹ yoo maa min nibẹ, awọn eniyan yoo jade ni aaye isiro ni ọtọọtọ lati ri awọn isẹ wọn eyiti wọn se ni ile aye.
فَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٍ خَيۡرٗا يَرَهُۥ 7
Ẹniti o ba se isẹ ni odiwọn awurebe kekere ninu awọn isẹ rere ati daadaa, yoo ri ni iwaju rẹ.
وَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖ شَرّٗا يَرَهُۥ 8
Ẹniti o ba si se isẹ ni odiwọn awurebe kekere ninu awọn isẹ buburu yoo ri bakanna.
سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye paapa ọmọniyan nibi awọn nkan akolekan ile aye rẹ, ki o le jẹ iranti fun un nipa ọjọ ọla rẹ ati itaniji fun un lati se atunse ibusẹrisi rẹ.
وَٱلۡعَٰدِيَٰتِ ضَبۡحٗا 1
Allah fi ẹsin ti o nrin, titi ti o fi ngbọ ohun lilekoko rinrin naa fun ara rẹ bura.
فَٱلۡمُورِيَٰتِ قَدۡحٗا 2
O si tun fi ẹsin eyiti o nko ina pẹlu awọn patako rẹ nigbati o ba kan apata nitori lilekoko atẹmọlẹ lori rẹ bura.
فَٱلۡمُغِيرَٰتِ صُبۡحٗا 3
O si tun fi ẹsin eyiti o bẹ si aarin awọn ọta ni asiko idaji bura.
فَأَثَرۡنَ بِهِۦ نَقۡعٗا 4
Ti wọn si ntu eruku pẹlu irin wọn.
فَوَسَطۡنَ بِهِۦ جَمۡعًا 5
Wọn si nbọ si aarin awọn ọta pẹlu awọn ẹsin wọn lapapọ.
Awọn keferi ni ẹda ti o buru ju ni adamọ, awọn olugbagbọ ododo si ni ẹniti o loore ju.
Ipaya Allah jẹ okunfa iyọnu Rẹ si ẹru Rẹ.
Jijẹri ilẹ lori awọn isẹ ọmọ Adamọ.