سورة (MAKIYYAH)
Fifi ije anabi Olohun rinle pelu awon eri, ati pipe awọn opuro sibi igbagbọ niti dida ẹru ba wọn.
الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡحَكِيمِ 1
(الٓر) (Alif Lam Rọọ) ọrọ ti rekọja lori iru rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ Bakọrah. Awọn aayah yii ti a ka ninu ọgba ọrọ naa jẹ awọn aayah alukuraani eyiti o ni ọgbọn ti o daju, ti o si kojọ lori awọn oye ati awọn idajọ.
أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ رَجُلٖ مِّنۡهُمۡ أَنۡ أَنذِرِ ٱلنَّاسَ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنَّ لَهُمۡ قَدَمَ صِدۡقٍ عِندَ رَبِّهِمۡۗ قَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٞ مُّبِينٌ 2
Se igbe eemọ dide fun awọn eniyan yoo wa maa bẹ lori wipe a sọ imisi Wa kalẹ fun ọkunrin kan ninu ọran wọn; ti a si pa a lasẹ ki o maa se ikilọ fun wọn kuro nibi iya Allah?! Fun niro - ire ojise - awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah pẹlu ohun ti yoo mu inu wọn dun; dajudaju ipo ti o ga lẹsan nbẹ fun wọn nitori isẹẹre ti wọn ti siwaju lọdọ Ọlọhun Ọba wọn ti mimọ nbẹ fun, awọn keferi sọ wipe: dajudaju ara kunrin yii ti awọn amin yii waa ba jẹ onidan ti o fi oju han.
إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۖ مَا مِن شَفِيعٍ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ إِذۡنِهِۦۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ 3
Dajudaju Ọlọhun Ọba yin - ẹyin ti ẹ nse eemọ yii - Oun ni Allah ti o da gbogbo sanmọ bi o se tobi to, ati ilẹ bi o se fẹ to fun ọjọ mẹfa lẹyin igba naa O ga, o si gun wa lori aga alaarasi naa, bawo ni ẹ se wa nse eemọ lori riran ọkunrin kan lati inu iran yin?! Oun nikan soso ni ẹniti O nse eto, ti O si nkadar ninu ọla Rẹ ti o gbaaye, kotọ fun ẹnikankan lati sipẹ lọdọ Rẹ ni ohun ki hun ayaafi lẹyin iyọnda Rẹ ati iyọnu Rẹ fun ẹniti o ba fẹ sipẹ, ẹniti a fi iroyin yii royin, Oun ni Allah tii se Ọlọhun Ọba yin, ki ẹ ya se afọmọ ijọsin fun Un lohun nikan, kilode ti ẹ ko gba awọn awijare ati awọn ẹri lori ijọkan soso Rẹ? ẹniti o ba ni igba isiti bioti wilẹ ki o kere, yoo mọ eleyi, yoo si gba a gbọ.
إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقًّاۚ إِنَّهُۥ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ 4
Ọdọ rẹ nikan ni isẹri si yin ni ọjọ igbende; ki O le san yin lẹsan lori awọn isẹẹ yin, Ọlọhun Ọba Allah se adehun fun awọn eniyan ni adehun ododo ti ko nii yapa rẹ, dajudaju O lagbara lori eleyi, O bẹrẹ dida ẹda lati ibi nkan ti ko si apejuwe kan siwaju, yoo tun waa daa pada lẹyin iku rẹ; ki Ọba ti mimọ nbẹ fun le sẹsan fun awọn ti wọn nigbagbọ si Allah, ti wọn si nse ọpọlọpọ isẹẹre pẹlu deedee ti ko nii din nkankan ku nibi daadaa wọn, ko si nii se alekun nibi asise wọn, sugbọn awọn ti wọn jẹ keferi si Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ nkan mimu kan nbẹ fun wọn ni eyiti o gbona tan yan an yan, ti yoo maaja ifun wọn, kiya itara si nbẹ fun wọn latara keferi wọn si Ọlọhun Ọba ati awọn ojisẹ Rẹ.
هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلشَّمۡسَ ضِيَآءٗ وَٱلۡقَمَرَ نُورٗا وَقَدَّرَهُۥ مَنَازِلَ لِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ يُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ 5
Oun ni ẹniti O se oorun ni nkan ti ntan imọlẹ, ti o si ntan ka, O si se osupa ni imọlẹ ti awọn eniyan nri imọlẹ nibẹ, O si se irin ajo rẹ ti ondinwọn onka ibusọ rẹ mejidin lọgbọn, ibusọ ni alafo ti o yoo rin ni ojumọ ati ni alẹ; ki ẹ le baa mọ - ẹyin eniyan - iye onka ọjọ latara oorun, ki ẹ si tun le ba mọ iye onka osu ati ọdun latara osupa, Ọlọhun Ọba Allah ko da gbogbo sanmọ ati ilẹ ati ohun ti nbẹ ninu mejeeji ayaafi pẹlu ododo; ki O le se afihan agbara Rẹ ati titobi Rẹ fun awọn eniyan, Ọlọhun Ọba Allah si nse alaye awọn ẹri ti o fi oju han ati awọn awijare ti o gbọngbọn lori ijọkan soso Rẹ fun awọn ijọ ti wọn mọ awọn ẹri ti o tọka si eleyi.
إِنَّ فِي ٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَّقُونَ 6
Dajudaju nibi pipaara orun ati ọsan fun awọn ẹru ati okunkun ati imọlẹ ti o tun nkun un, ati kikuruikinni keji wọn ati gigun rẹ ati awọn ẹda ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ jẹ awọn amin ti ntọka si agbara Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ijọ ti wọn npaya Allah nibi itẹle awọn asẹ Rẹ ati ijinna si awọn nkan ti O kọ.
Fifi jijẹ anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun rinlẹ ati wipe isẹ ti a ran jẹ alamọri ti mọgbọn wa, ti ko si eemọ nibẹ.
Dida gbogbo sanmọ ati ilẹ ati gbogbo ohun ti nbẹ ninu awọn mejeeji ati didari alamọri ati pipebubu awọn asiko ati yiyapa si ara wọn oru ati ọsan, gbogbo rẹ jẹ awọn amin ti o tobi, ti o si ntọka si ijẹ Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun.
Ipẹ ni ọjọ igbende ko nii bẹ ayaafi awọn ti Allah ba yọnda fun, ti o si yọnu si ọrọ rẹ ati isẹ rẹ.
Pipebubu Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun lori igbesẹ oorun ati awọn aaye isọkalẹ si osupa, o su ikunlọwọ lori mimọ awọn isẹlẹ, awọn onka ọjọ ati awọn ọdun.